Ẹká àbọ̀ sí apu #KnowYourRightsNigeria
A ti túmọ̀ àwọn ẹ̀tọ́ yi ní ọ̀nà tí ènìyàn lè fi ri kà nígbàkugbà nípasẹ̀ títẹ bọ́tìnì fóònù lọ́wọ́ waa. ọ̀pọ̀lọpọ̀ waa ló nbẹ̀rù àwọn agbófinró. Ìbẹ̀rù nwáyé nítorí àìmọ̀n ẹ̀tọ́ waa. Apu yi yóò fi gbogbo ẹ̀tọ́ wa hàn wá labẹ òfin Orílẹ̀ èdè Nàìjíríà, yóò sì fùn enìkọ̀ọ̀kan ní oun tí ó nílò láti dúró sinsin àti láti dáàbò bo ara rẹ̀ lòdì sí ìyànjẹ.
#KnowYourRightsNigeria jẹ́ àkànse isẹ́ Constitutional Rights Awareness and Liberty Initiative (CRALI).
Ìrànwọ́ òfin láti ilé isẹ́ ìmòfin ti ADEOLA OYINLADE & CO
Pẹ̀lu àfọwọ́sowọ́pọ̀ U.S Consulate General
Lagos àti PEMORAD DIGITAL TECHNOLOGIES LTD
Tẹ èyíkèyí nínu àwọn ẹ̀tọ́ tí ó wà nísàlẹ̀ yí, yóò se àfihàn àwon ẹ̀tọ́ tí ó jọjú ti o lè se àmúlò rẹ̀.
A ti pèsè sílẹ̀ ibi tí o tì lè bá àwọn Amòfin sọ̀rọ̀ nípa ìbéèrè lórí ẹ̀tọ́ rẹ nígbàkùgbàà. Ọ̀fẹ́ ni àwọn Amòfin yóò dáhùn ìbéèrè rẹ. O tún lè fi àwòrán nípa ẹ̀tọ́ ọmọ ènìyàn sí inú apu yí kí àwọn ènìyàn wóò tàbí sọ̀rọ̀ nípa rẹẹ̀.
Rántí wípé àwọn Amòfin wa ni yóò dáhùn sí ìbéèrè nípa ẹ̀tọ́ ọmọ ènìyàn nìkan. Àwọn Amòfin wa kì yóò dáhùn sí ìbéèrè nípa okòwò, ìfowópamó, ìkẹ́rù wọlé lati òkè òkun tàbí ọ̀rọ̀ òfin míràn nípa okòwò. Tóò bá ní ìbéèrè nípa òfin okòwò, lọ rí Amòfin rẹ̀ẹ.
A ti pèsè sínú apu yí ibi tí o ti lè ké gbàjarì tàbí sọ fún ẹ̀ka ìjọba tí ẹnikẹ́ni bá tẹ ẹ̀tọ́ rẹ lójú. Wọn yóò gbé ẹ̀sùn rẹ yẹ̀wò.
Ní ìgbàkugbà tí o bá ti ní ìmọ̀ àti òye ẹ̀tọ́ rẹ nípasẹ̀ apu #KnowYourRightsNigeria, ìyànjú wa ni wípé kí o jẹ́ kí àwọn Amòfin rẹ se ìtọ́ni rẹ ní ìgbà gbogbo. Má se rò wípé o ti mọ gbogbo òfin ẹ̀tọ́ rẹ pátápátá lẹ́hìn to bá ti ka ọ̀rọ̀ inú apu yi.