25(1) O lè jẹ́ ọmọ bíbí orílẹ̀ èdè Nàìjíríà nípasẹ̀ ibi tí:

  1. a) wọ́n bá bí ẹ ní Nàìjíríà síwájú ọjọ́ kiní oṣù kẹ̀wá ọdún 1960 tàbí tí bàbá, ìyá, tàbí ìyá bàbá, ìyá màmá, bàbá bàbá tàbí bàbá ìyá rẹ jẹ́ ọmọ ìlú kan ní Nàìjíríà. Ṣùgbọ́n, o kì yóò jẹ́ ọmọ orílẹ̀ èdè yí tí wọ́n kò bá bí àwọn òbí rẹ tàbí àwọn òbí-òbí rẹ ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà.
  2. b) wọ́n bá bí ẹ ní orílẹ̀ èdè míìràn lẹ́yìn ọjọ́ kiní, ọ̀sẹ̀ kẹwà ọdún 1960, àti wí pé ìyá rẹ tàbí bàbá rẹ, tàbí àwọn òbí bàbá tàbí ìyá rẹ jẹ́ ọmọ Nàìjíríà.
  3. c) A bí ẹ ní orílẹ̀ èdè míìràn ṣùgbọ́n, bàbá tàbí ìyá rẹ jẹ́ ọmọ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà.

26(1) O lè jẹ́ ọmọ Nàìjíríà nípasẹ̀ fífi orúkọ sílẹ̀ ṣùgbọ́n, kí o tó lè ṣe èyí, o gbọ́dọ̀ jẹ́ ìwọ̀nyí:

  1. a) oníwà rere;
  2. b) o gbọ́dọ̀ fi ìwà hàn pé o fẹ́ maa gbé ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà;
  3. c) O gbọ́dọ̀ ṣe Ìbúra láti bọ̀wọ̀ fún òfin Nàìjíríà àti láti dá àbò bó.

(2) Apá òfin yìí bá ẹ wí tí o bá jẹ́:

  1. a) obìnrin tí ó fẹ́ ọmọ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà
  2. b) a bí ọ ní orílẹ̀ èdè míìràn ṣùgbọ́n àwọn òbí- bàbá tàbí ìyá rẹ jẹ́ ọmọ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà.

27 (1) O lè jé ọmọ orílẹ̀ èdè yíì nípasẹ̀ ìdarapọ̀ tó bá kún ojú òṣùwọ̀n; o lè bèrè fún ìwé ẹ̀rí ìdarapọ̀ láti jẹ ọmọ orílẹ̀ èdè yíì lọ́dọ̀ Ààrẹ Nàìjíríà.

(2) o lè bèrè fún ìdarapọ̀ láti jẹ́ ọmọ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà àyàfi tí o bá tẹ́ Ààrẹ lọ́rùn wí pé:

  1. a) o ti pé ọmọ ọdún méjìdínlógún àti sókè;
  2. b) o jẹ́ oníwà rere;
  3. c) O ti fihàn wí pé o fẹ́ maa gbé ní Nàìjíríà;
  4. d) Nípasẹ̀ Ìwádìí Gómínà Ìpínlẹ̀ tí o ń gbé, o fihàn wí pé agbègbè tí o ń gbé gbà ọ́, o sì ti mo ìgbé ayé àwọn ènìyàn níbi tí o ń gbé, àti wí pé, o fẹ́ maa gbé ìlú náà.
  5. e) ó tó láti mú tàbí ó ti ń mú ìtẹsíwájú bá ìrànwọ́ ìtẹsíwájú Nàìjíríà;
  6. f) ó tí ṣe ìbúra láti bọ̀wọ̀ fún ìwé òfin Nàìjíríà àti láti dábò bò.
  1. g) kí ó tó bèrè, ó ti gbé ní Nàìjíríà fún ọdún márùndínlógún, tàbí ó ti gbé láì kúrò ní Nàìjíríà fún oṣù méjìlá àti láàrin ogún ọdún kó tó bèrè fún ìdarapọ̀ náà, tí ó sì ti gbé ní orílẹ̀ èdè yíì fún ọdún márùndínlógún lápapọ̀.

28(1) O kì yóò jẹ́ ọmọ Nàìjíríà mọ́ tí o kò bá jẹ́ ọmọ bíbí orílẹ̀ èdè yíì tí o tún gba ìjẹ́ ọmọ ìlú orílẹ̀ èdè míìràn nípasẹ̀ ìforúkọ sílẹ̀ tàbí ìdarapọ̀.

(2) tí o bá kìíṣe ọmọ bíbí orílẹ̀ èdè míìràn tí o sì fẹ́ jẹ́ ọmọ Nàìjíríà nípa ìforukọsílẹ̀ tàbí ìdarapọ̀, ìjẹ́ ọmọ Nàìjíríà rẹ ní yóò ní ìdánwò àti gbèdeke títí da àsìkò tí o kéde wí pé o kìíṣe ọmọ orílẹ̀ èdè míìràn mọ́. Èyí ni o gbọ́dọ̀ ṣe láàrín oṣù méjìlá ní ìgbà tí o di ọmọ Nàìjíríà nípasẹ̀ ìforukọsílẹ̀ tàbí ìdarapọ̀.

29(1) Àgbàlagbà tó bá tó ọmọ ọdún méjìdínlógún tí kò fẹ́ jẹ́ ọmọ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà mọ́ lè kéde èróńgbà rẹ̀ ní ọ̀nà wọ̀nyí.

(2) Ààrẹ Nàìjíríà yóò jẹ́kí ìkéde náà wà ní àkọsílẹ̀. Tí ó bá ti wà ní àkọsílẹ̀, ẹni tó ṣe ìkéde náà kòní jẹ́ ọmọ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà mọ́.

(3) Ààrẹ Nàìjíríà lè má jẹ́kí ìkéde náà wà ní àkọsílẹ tí:

  1. a) Tí ìkéde náà bá wáyé ní ìgbà tí ogun ńjà ní Nàìjíríà tàbí
  2. b) Tí Ààrẹ bári wí pé àkosílẹ̀ náà kì ìṣe fún àǹfàní Nàìjíríà.

(4) Kí ènìyàn tó lè jẹ́ àgbàlagbà bí a se kọ́ ní apá kọkàndínlọ́gbọ̀n àti óókan kékeré 29(1) apá òfin yìí, ẹni náà ti tó ọmọ ọdún méjìdínlógún sókè

  1. b) Ìyawó ilé àgbàlagbà jẹ́ eni tó tí tó ọdún méjìdínlógún sókè.

30 (1) Ààrẹ lè dá ẹni tó ti gba ìdarapọ̀ láti jẹ́ ọmọ Nàìjíríà dúró tí Ààrẹ bá ri wí pé láàrín ọdún méje tó ti darapọ̀ láti jẹ́ ọmọ orílẹ̀ èdè yíì, ó ti gba ìdajọ́ ẹ̀wọ̀n ọlọ́dún mẹ́ta sókè.

(2) Ààrẹ lè dá ẹni tó gba ìwé jíjẹ́ ọmọ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà dúró tí Ààrẹ bá ri wí pé nínu ìkọsílẹ̀ ilé ẹjọ́ gíga tàbí nínu ìwádìí, ẹni náà wu ìwà tàbí sọ̀rọ̀ tí kìíṣe olóotó sí Nàìjíríà tàbí ní ìgbà tí Nàìjíríà ńja ogun, ẹni náà ní àṣepọ̀ pẹ̀lú àwọn ọ̀tá lòdì sí Nàìjíríà. Irú ẹni bẹ́è kò gbọdọ̀ jẹ́ ọmọ bíbí Nàìjíríà.

31 (1) Ní apá òfin yíì, òbí tàbí àwon òbí-òbí ènìyàn yóò jẹ́ ọmọ Nàìjíríà tóbá jẹ́ wí pé ní ìgbà tí wọ́n bí wọn, wọ́n kún ojú òṣùwọ̀n láti jẹ́ ọmọ bíbí Nàìjíríà tó bá jẹ́ wí pé wọ́n wà láyé ní Ọjọ́ kiní, Oṣù kẹwà ọdún 1960.

32 (1) Ààrẹ lè ṣe ìlànà ní ìbámu pẹ̀lú apá òfin yìí láti mú ohun tó wà nínu ìwe òfin yìí ṣe àti láti fún àwọn aya àti ọkọ ọmọ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà láti orílẹ̀ èdè míìràn gbé ní Nàìjíríà bí wọ́n kò bá fẹ́ jẹ́ ọmọ orílẹ̀ èdè yíì.

(2) Gbogbo ìlànà tí Ààrẹ bá ṣe ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ apá òfin yìí ní ó gbọ́dọ̀ fi ṣọwọ́ sí Ilé Ìgbìmọ̀ Aṣòfin Àpapọ̀.

 

Lábẹ́ ọ̀rọ̀ òfin yìí, gbogbo ọmọ Nàìjíríà ni ó ní ẹ̀tọ́ láti rà tàbí ní dúkíà tó wà ní ojú kan àti èyí tó ṣe múrìn káàkiri ní Nàìjíríà.

(44) (1) kòsí ẹni tó gbọ́dọ̀ fi ipá gba dúkíà ẹnikẹ́ni tó wà lójúkan tàbí tí o ń rìn láìṣẹ̀ nípa ọ̀nà tí òfin là kalẹ̀ ní Nàìjíríà wọ̀nyí-

(a) sísan ní kíákíá owó ìtẹ̀lọ́rùn fún ẹni tí ó ní dúkíà; àti

(b) fífún ẹni tó ní dúkíà ní àyè láti ṣe òdinwọ̀n iye owó tó yẹ kó gbà ní ilé ẹjọ tàbí ìgbìmọ̀ ìdajọ́ ní àgbègbè náà ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà.

(2) kòsí ohun kankan ní apá kékeré àkọkọ́ (1) òfin yìí tí a lè túmọ̀ láti yẹ̀yẹ́ òfin míìràn-

(a) nípa pé kí ènìyàn san owó orí tàbí owó míìràn àti ojúṣe rẹ̀;

(b) fún dídá sèríà tàbí gbígba dúkíà ẹni fún títẹ òfin lójú bójẹ́ ti ará ìlú tàbí fún ti ìjẹbi ẹ̀sùn;

(c) tó fara pẹ́ fífí ilé yáni, ìyálégbé, ìyàwó, ìsanwó, owó tí ó wọlé nípa gbígba iṣẹ́ ṣíṣe

(d) tó fara pẹ́ fífún ni ní ògùn ẹni tàbí tó jẹ gbèsè àti ti ilé iṣẹ́ tó ń kógbá wọlé;

(e) tó fara pẹ́ àmuṣẹ ìdájọ́ ilé ẹjọ́;

(f) gbígba dúkíà tó wà ní ipò ìjàm̀bá tàbí tó lè mú ìjàm̀bá bá ìlera àwọn ènìyàn, ọ̀gbìn àti ẹranko,

(g) tó níṣe pẹ̀lú dúkíà;

(h) tó níṣe pẹ̀lú Asojú;

(i) tó níṣe pẹ̀lú àwọn ìdáwọ́ dúró;

(j) tó níṣe pẹ̀lú dúkíà tó ilé iṣẹ́ tó dá dúró ní ti wọ́n dásílẹ̀ lábẹ́ òfin Nàìjíríà.

(k) tó níṣe pẹ̀lú gbígba dúkíà ní ìwọnba ìgbà ràm̀pẹ́ nípasẹ̀ ṣíṣe àyẹ̀wò, ìwádìí tàbí ìbéérè;

(i) tó níṣe pẹ̀lú ṣiṣe iṣẹ́ lórí ilé fún àbò ilẹ̀ (soil); tàbí

(m) fún ní sísan owó gbà má binú láì fi àsìkò ṣòfò sí bíba ilẹ̀ jẹ́, igi olówó iyebíye tàbí ọ̀gbìn, gbígba ìjọba tàbí ẹnikẹ́ni láyè láti wólé, gbélé, tàbí gbíngbìn, kíkó, ríri òpó, wàyá, páìpù, tàbí ohun míìràn sórí ilẹ̀ láti ṣe tàbí kó ọjà epo, omi, kóótà, ìṣe ìbára ẹnisọrọ̀ tàbí ohun amáyédẹrùn.

(3) bí òfin yìí ti sọ, gbogbo dúkíà àti ìṣàkóso gbogbo àlùmọ́nì, àlùmọ́nì epo, gáásì, tó wà lóri ilẹ̀ tàbí abẹ́ ilẹ̀, tàbí lórí omi tàbí abẹ́ omi tó wà ní àgbègbè ọ̀rọ̀ ajé orílẹ̀ èdè Nàìjíríà ni yóò jẹ́ ti ìjọba Nàìjíríà tí ìsàkoso rẹ̀ yóò jẹ́ bí àlàkalẹ̀ ilé ìgbìmọ̀ Aṣòfin Àpapọ̀ ti wí.

(1) Nítorí ẹ̀yà, ìlú, jíjẹ́ ọkùnrin tàbí obìnrin, ẹ̀sìn, èrò ènìyàn nípa òṣèlú, a kò gbọ̀dọ̀ ṣe àwọn ǹnkan wọ̀nyí fún àwọn ọmọ orílẹ̀ èdè yíì:

  1. a) ìṣe ojúsajú tàbí ìyanje fún enìkan tí a kò ṣe sí ẹnìkejì nítorí ọ̀rọ àgbègbè kan, ẹ̀yà, ìlú, ìjẹ́ ọkùnrin tàbí obìnrin, ẹ̀sìn tàbí èrò nípa òṣèlú rẹ̀.
  2. b) ṣíṣe ojúṣajú ní ọ̀nà tí àwọn míìràn kò rígbà ní àgbègbè kan nítorí ẹ̀yà, ìlú abínibí, ìjẹ́ ọkùnrin tàbí obìnrin tàbí èrò nípa ọ̀rọ̀ òṣèlú.

2) kòsí ọmọ Nàìjíríà kan tí a gbọ́dọ̀ fi  ẹ̀tọ́ rẹ̀ dùn torí ipò bí wọ́n ṣe bi.

(3) kòsí ohun kankan ní apá kékeré àkọkọ́ (1) òfin yìí tí ó ṣe ìyẹpẹrẹ òfin míìràn tó fi òdinwọ̀n sí ìyànsípò àwọn ènìyàn sí ipò lábẹ́ ìjọba tàbí ti Ológun tàbí ti Ọlọ́pà tàbí ipò ilé iṣẹ́ tí ó di àgbékalẹ̀ lábẹ́ òfin Nàìjíríà.

(1) Gbogbo ọmọ Nàìjíríà ni o ní ẹ̀tọ́ láti rìn káàkiri Nàìjíríà àti láti gbé ní agbegbè Nàìjíríà. Kòsí ọmọ orílẹ̀ èdè yíì tí a gbọ̀dọ̀ mú kúrò ní Nàìjíríà tàbí dènà rẹ̀ láti wọlé tàbí jáde kúro ní Nàìjíríà.

2) kòsí ǹnkankan nínu apá kékeré òfin àkọkọ́ (1) yíì tó tako òfin tí ó ṣe pàtàkì ní àgbègbè àwarawa bí:-

  1. a) kí wọ́n ṣe ìdaduró tàbí láti ma ṣe ìrìn káàkiri ènìyàn tó wùwà ọ̀daràn tàbí tí wọ́n fura sí wí pé ó dáràn láti máṣe gbà láyè láti sá kúrò ní Nàìjíríà.
  2. b) bí kí wọ́n dá ènìyàn padà láti Nàìjíríà lọsi orílẹ̀ èdè míìràn:

(i) láti kọju ìgbẹ̀jọ́ ìwà ọ̀daràn tí wọ́n fi kàn, tàbí

(ii) láti ṣẹ̀wọ̀n fún ìdajọ́ lórílẹ̀ èdè míìràn tí o ti dáràn tó tún jẹ̀bi ní orílẹ̀ èdè ti Nàìjíríà bá ní àdéhùn lórí irúfẹ́ ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀.

gbogbo ènìyàn ló ní ẹ̀tọ́ láti kóra jọ ní ìrọrùn àti darapọ̀ láti dá ẹgbẹ́ òṣèlú sílẹ̀, ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́, tàbí ẹgbẹ́ míìràn fún ààbò ànfàní wọn. Ìdí fún ẹ̀tọ́ yìí nínu apá ọ̀rọ̀ iwé òfin yìí kò gba agbára ti ìwé òfin yìí fún Àjọ Elétò Ìdìbò INEC lóri àwọn ẹgbẹ́ òṣèlú èyi tí kò fowosí.

(1) gbogbo ènìyàn ló ní ẹ̀tọ́ láti fi ọ̀kàn rẹ̀ hàn àti ìwòye, ó lè gbà tàbí fúnni ní èrò tàbí ìròyìn láì dá dúró.

2) pẹ̀lú ọ̀rọ̀ ìwé òfin yìí, gbogbo ènìyàn ni o ní ẹ̀tọ́ láti ṣe ìdasílẹ̀ àti ṣíṣe iṣẹ́ ohun ìgbé ìròyìn àti ẹ̀rọ síta ní ọ̀nà wí pé:

Kòsí ẹnikẹ́ni tí ó lè dá ilé iṣẹ́ tẹlifísàn tàbí ìgbóhùnsáféfé sílẹ̀ yàtọ̀sí Ìjọba àpapọ̀ àti ìpínlẹ̀ tàbí ẹni tí Ààrẹ orílẹ̀ èdè bá gbà láyè nígbà tí wọ́n bá ti tẹ̀lé òfin.

3) kòsí ǹnkankan nínu apá òfin yìí tó tako òfin tí ó ṣe pàtàkì ní àgbègbè àwàrawa.

(a) láti ma ṣe jẹ́kí àwọn ènìyàn ṣe àfihàn àwọn ọ̀rọ̀ tí ó yẹ kó pamọ́, láti mú ìtẹsíwájú bá òmìníra ilé ẹjọ́ nípa fífi òfin ṣe ìlò ẹrọ ìbánisọ̀rọ̀, ìgbóhùn sáfẹ́fẹ́, tẹlifísàn tàbí àfihàn àwòrán tàbí

(b) lórí fífi òfin de ẹni tó wà ní ìpò ìjọba àpapọ̀ tàbí ìpínlẹ̀, ọmọ ẹgbẹ́ Ológun tàbí ti Ọlọ́pà tàbí àjọ agbófinró ìjọba tí òfin gbékalẹ̀.

(1) gbogbo ènìyàn ni ó ní ẹ̀tọ́ láti ronú tàbí ìwoye tó wù, tàbí yan ẹ̀sìn, yíì ẹ̀sìn rẹ̀ padà, tàbí ṣe ẹ̀sìn àti ìpòlongo ẹ̀sìn pẹ̀lú àwọn ènìyàn tàbí tìkara rẹ̀ nípasẹ̀ ìwásù, ẹ̀kọ́, tàbí ìjọsìn.

2) kòsí ilé ìwé tó gbọ́dọ̀ fi ipá mú akẹ́ẹ̀kọ̀ láti gba ìlanà ẹ̀sìn tàbí kópa nínu àjọyọ̀ ẹ̀sìn ti ìlànà rẹ̀ yatọ̀sí ti akẹ́ẹ̀kọ̀ náà tàbí yàtọ̀sí ẹ̀sìn ti àwọn òbí tàbí alágbàtọ́ rẹ̀ fọwọsí.

3) a kò gbọ̀dọ̀ dá àgbègbè ẹ̀sìn tàbí ẹ̀sìn kan dúró láti fún àwọn akẹ́ẹ̀kọ̀ àgbègbè náà tàbí ẹ̀sìn náà ní ìlànà ti àgbègbè tàbí ilé ẹ̀kọ́ ẹ̀sìn náà ńṣe àkóso rẹ̀.

4) kòsí ẹni tó ní ẹ̀tọ́ láti darapọ̀ mọ́ àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òkunkùn.

gbogbo ọmọ Nàìjíríà ni o ní ẹ̀tọ́ sí ààbò ìpamọ́; ìpamọ́ ilé, ìpamọ́ gbogbo ìbánisọ̀rọ̀ bí lẹ́tà, ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀, ẹ̀rọ ìfìweránṣẹ́ tẹligíráfù.

(1) Láti ṣe ìdajọ́ lóri ẹ̀tọ́ àti ojúṣe ọmọ Nàìjíríà, ẹni náà gbọ́dọ̀ ní ànfàní láti sọ ti ẹnu rẹ̀ ní àsìkò tó mọ́gbọ́n wá ní ilé ẹjọ́ tàbí àjọ ìdajọ́.

(2) Ṣùgbọ́n, a kò gbọ̀dọ̀ sọ wí pé òfin kò múnádóko tóri wí pé o fún ìjọba tàbí aṣàkoso ní agbára láti ṣe ìgbẹ́jọ́ àti ìdájọ́ tó níṣe pẹ̀lú ẹ̀tọ́ àti ojúṣe ènìyàn tí òfin náà bá fun:

(a) ẹni náà ní ànfàní láti sọ ti ẹnu rẹ̀ ní iwájú àwọn ìgbìmọ̀ tó fẹ́ ṣe ìdájọ́ rẹ̀; àti

(b) ìdájọ́ ìgbìmọ̀ náà ni agbára tó jùlo tí ẹnikẹ́ni kòní lè fi pe ẹjọ́ kòtẹ́mi lọ́rùn lórí ìdájọ́ náà.

3) tí ìdájọ́ kò bá ṣókùkùn àti ìgbẹ́jọ́ lórí àwọn ọ̀rọ̀ tí ó wà ní apá òfin yíì bóyá ní ilé ẹjọ́ tàbí ìgbìmọ̀ ìgbẹ́jọ́.

4) tí a bá mú ẹnikẹ́ni lọ sílé ẹjọ́ lórí ẹ̀sùn ọ̀daràn, ẹni náà ní ẹ̀tọ́ láti sọ tẹnu rẹ̀ ní gbangba ní àkókò tó mọ́gbọ́n wá ṣùgbọ́n ó lè má ṣééṣe ní àsìkò wọ̀nyí:

(a) ilé ẹjọ́ lè má gbà láyè àwọn tí kòní ṣe pẹ̀lú ẹjọ́ náà, tàbí amòfin àwọn tí ọ̀rọ̀ kàn tí ó bá ma ṣe jàm̀bá fún ààbò àti àlààfíà ìlú tàbí ààbò àwọn tí kó tí tò ọdún méjìdínlógún, ìdábò bò àyè àwọn tí ọ̀rọ̀ kàn tàbí ìdí míìràn tí ó ṣe pàtàkì lórí ọ̀rọ̀ náà.

(b) ní àkókò ìgbẹ̀jọ́, tí mínísítà ìjọba àpapọ̀ tàbí kọmísọ́nà ìpínlẹ̀ bá te ilé ẹjọ́ tàbí ìgbìmọ̀ ìgbẹ̀jọ́ lọ́rùn wí pé tí ìgbẹ̀jọ́ àti ẹ̀rí bá wáyé ní gbangba, ó léwu fún ìlú; ilé ẹjọ́ tàbí ìgbìmọ̀ ìgbẹ̀jọ́ yóò ṣe ìgbésẹ̀ láti gba ẹ̀rí náà ní ìkọ̀kọ̀.

5) Ẹnikẹ́ni tí a bá mú wá síle ẹjọ́ fún ẹ̀sun ọ̀daràn ní ójẹ́ aláìṣẹ̀ àyàfi tí ilé ẹjọ́ sọ wí pé ó jẹ̀bi ẹ̀sùn náà.. Ìdí ni wí pé, àwọn ẹ̀ka òfin yìí kò fagilé àwọn òfin kọ̀ọ̀kan tó ní kí olùjẹ́jọ́ kó ṣe àlàyé àwọn ẹ̀sùn tán fi kàn.

6) Gbogbo ẹni tí wọ́n bá gbé lọsí ilé ẹjọ́ fún ẹ̀sùn ọ̀daràn ní àwọn ẹ̀tọ́ wọ̀nyí:

(a) ẹ̀tọ́ láti gbọ́ irú ẹ̀sun tán fi kàn ní èdè tó gbọ́ àti ní àkokò.

(b) ẹ̀tọ́ fún àkókò tó dára àti ìṣe láti gbaradì fún ẹjọ́ rẹ̀

(c) ẹ̀tọ́ láti gbé ẹjọ́ rẹ̀ kalẹ̀ fún ara rẹ̀ tàbí láti ọ̀dọ̀ amòfin rẹ̀

(d) ẹ̀tọ́ láti tó láti pe àwọn ẹlẹ́rì rẹ̀ àti láti bèrè lọ́wọ́ àwọn tí wọ́n kówá láti ṣe ẹlẹ́rì lòdì si.

(e) ní ẹ̀tọ́ sí ogbùfọ̀ láìsan owó tí kò bá ní òye èdè ilé ẹjọ́.

7) tí ènìyàn bá ń kojú ìgbẹ́jọ́ ẹ̀sùn ọ̀daràn, ilé ẹjọ́ tàbí ìgbìmọ̀ ìgbẹ́jọ́ gbọ́dọ̀ fi àkoolé ìgbẹ́jọ́ sí ìpamọ́ tó dára. Olùjẹ́jọ́ tàbí ẹnikẹ́ni tó bá yàn ní ẹ̀tọ́ létí gba ẹ̀dà ìwé ìdajọ́ náà láàrin ọjọ́ méje tí ẹjọ́ náà bá parí.

8) kòsí ẹnikẹ́ni tí yóò jẹ̀bi ẹ̀sùn òhun tó ṣe tàbí kòṣe nígbà tó jẹ́ wí pé ẹ̀sùn náà kò tí di ẹ̀sùn ọ̀daràn ní àkókò tí ó ṣe tàbí kò ṣe ohun tó yẹ kóṣe. Kò gbọ̀dọ̀ sí ìjìyà fún ìwà ọ̀daràn tó pọ̀jù èyí tí òfin sọ nígbà tí ìwà ọ̀daràn bẹ́ẹ̀ wáyé.

9) ẹnikẹ́ni tó bá lè ṣe àfihàn wí pé ilé ẹjọ́ ìjọba tàbí ìgbìmọ̀ ìdájọ́ ti gbọ́ ẹjọ́ kan nípa ohun tí wọ́n si tì fún ohun ní ìdáláre tàbí ẹbi ni kò gbọ̀dọ̀ jẹjọ lóri ọ̀rọ̀ náà mọ́ àyàfi ní ilé ẹjọ́ tó gaju èyí tí ó ṣe ìdájọ́ náà lọ.

10) enikẹ́ni tí ìjọba bá dáríjìn fún ẹ̀sùn ọ̀daràn ni a kò gbọdọ̀ gbé lọ sí ilé ẹjọ́ lóri ẹ̀sùn náà mọ́.

11) enikẹ́ni tó bá ti kojú ìjẹ́jọ lóri ẹ̀sùn ọ̀daràn ni a kò gbọ̀dọ̀ fi ipá mú láti ṣe àlàyé ohun tó ṣẹlẹ̀ ní ilé ẹjọ́.

12) Kòsí enikẹ́ni tí wọ́n gbọ́dọ̀ dá lẹ́bi fún ẹ̀sùn ọ̀daràn yàtọ̀ sí bí ìwé òfin yìí ti làkalè.

(1) gbogbo ènìyàn ló ní ẹ̀tọ́ láti káàkiri àti wí pé a kò gbọdọ̀ dá òmìnira ẹnikẹ́ni dúró àyàfi ní àwọn ọ̀nà wọ̀nyí tí òfin làkalẹ̀:

  1. a) tí ẹni náà bá gba ìdajọ́ ilé ẹjọ́ torí wí pé ó jẹ̀bi ẹ̀ṣùn ìwà búburú;
  2. b) tí ẹni náà bá kùnà sí àṣẹ ilé ẹjọ́ tàbí tí wọ́n bá fẹ́ jẹ́kí àṣẹ ilé ẹjọ́ kó wá sí ìmúṣẹ lórí ẹni náà.
  3. c) tí wọ́n bá fẹ́ mú ẹni náà wá sí ilé ẹjọ́ ní ìbámu pẹ̀lú àṣẹ ilé ẹjọ́ tàbí wí pé ẹni náà dáràn tàbí ó fẹ́ dáràn;
  4. d) fún ààbò àti ẹ̀kọ́ ẹni tí ọjọ́ orí rẹ̀ kò tí tò ọmọ ọdún méjìdínlógún;
  5. e) fún ìdí Pàtàkì bì ẹ̀tọ́ ìlera fún ẹni tó ńṣe àìsàn tó lè ran ọ̀pọ̀ ènìyàn, wèrè, ẹni tó ń mu ogùn olóró tàbí láti dá ààbò bo àgbègbè;
  6. f) láti dènà ènìyàn tó fẹ́ wọ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà láì bá òfin mu, tàbí dá ẹni tó wọ Nàìjíríà padà láì bá òfin mu tàbí láti ṣe ìgbésẹ̀ lórí ìwọlé àti ìdápadà ẹni tí kò bá òfin mu;

àti wí pé ẹni tí wọ́n fi sí àhamọ́ fún ẹ̀sùn kan tàbí nítorí wí pé o ń dúró de ìdajọ́ kò gbọdọ̀ wà ní àhamọ́ ju iye ọjọ tí òfin so wí pé kí ó dúró tó bá jẹ̀bi ẹ̀sùn náà.

2) ẹni tí wọ́n bá fi òfin mú tàbí tì mọ́lé ní ẹ̀tọ́ láti panumọ́ tàbí kó má ṣe ṣe ìdáhùn ìbéèrè àyafi tí ó bá ti bá agbẹjọ́rò rẹ̀ sọ̀rọ̀ tàbí ẹni tó bá yàn láti bá sọ̀rọ̀.

3) Ẹni tí wọ́n bá fi òfin mú tàbí tì mólé ni wọ́n gbọ́dọ̀ sọ fún ní kíkọ sílẹ̀ ìdí tí wọ́n ṣe mu tàbí tì mọ́lé láàrín wákátì mẹ́rìnlélógún ní èdè tí ó gbọ́.

4) ẹni tí wọ́n bá fi òfin mú tàbí tì mọ́lé fún ìwà ọ̀daràn tàbí fún ìfura pé ó wu ìwà ọ̀daràn ni wọ́n gbọ́dọ̀ mú lọsí ilé ẹjọ́ ní àkókò tó mọ́gbọ́n wá, àti tí wọ́n kò bá mú lé ilé ẹjọ́, ó gbọ́dọ̀ jẹjọ́ ní àkókò wọ̀nyí:

  1. a) lẹ́yìn òṣù méjì tí wọ́n ti fi òfin mu tàbí tì mọ́lé tí kòsí ní ẹ̀tọ́ fún ìtúsílẹ̀ oní gbèdéke.
  2. b) lẹ́yìn oṣù mẹ́ta tí wọ́n ti fi òfin mu tàbí tì mọ́lé, tí wọ́n ti fi sílẹ̀ pẹ̀lú gbèdéke, ó gbọ́dọ̀ gba ìtúsílẹ̀ láìsí gbèdéke tàbí gbèdéke tó ṣe pàtàkì láti mú kí ó yojú fún ẹjọ́.

(5)  ìtumọ̀ ‘àkókò tó mọ́gbọ́n wá’ tó wà ní apá kékeré kẹrin (4) ni:

  1. a) ọjọ́ kan, tí ilé ẹjọ́ tó súnmọ́ ibi tí wọ́n ti fi òfin mu tàbí àtìmọ́lé kò ju ìwọ̀n rédíọ́sì ogójì lọ.
  2. b) ọjọ́ méjì tàbí iye ọjọ́ tí ilé ẹjọ́ ti rò wí pé ó mọ́gbọ́n wá.

(6) enikẹ́ni tí wọ́n bá mú tàbí tì mólé lòdì sí òfin ni yóò ní ẹ̀tọ́ sí owó gbà mábinú àti ẹ̀bẹ̀ àforíjìn láti ọ̀dọ̀ àwọn aláṣẹ tàbí ẹni tí òfin sọ wí pé ó gbọ́dọ̀ ṣe bẹ́ẹ̀.

(7) a kòní ṣe ìtumọ̀ ẹka òfin yìí fún:

  1. a) pàápàá jùlo apá kékeré ìkẹrin (4) apá ìwé òfin yìí wà fún ẹni tí wọ́n mú tàbí tì mọ́lé lóri ẹ̀sùn ìwà ọ̀daràn tó burú jùlọ (capital offence); àti
  2. b) fún àtìmọ́lé tí kòju oṣù mẹ́ta fún ọmọ ẹgbẹ́ ológun ilẹ̀ yíì (armed force) tàbí ti Ọlọ́pàá lóri ìmúṣẹ ìdajọ́ ti Ológun tàbí ti Ọlọ́pàá dá lórí ẹ̀sùn àtimọ́lé tí ó sì jẹ̀bi rẹ̀.