Entries by KnowYourRightsNigeria

Bí ènìyàn se lè jẹ́ ọmọ Orílẹ̀ èdè Nàìjíríà

25(1) O lè jẹ́ ọmọ bíbí orílẹ̀ èdè Nàìjíríà nípasẹ̀ ibi tí: a) wọ́n bá bí ẹ ní Nàìjíríà síwájú ọjọ́ kiní oṣù kẹ̀wá ọdún 1960 tàbí tí bàbá, ìyá, tàbí ìyá bàbá, ìyá màmá, bàbá bàbá tàbí bàbá ìyá rẹ jẹ́ ọmọ ìlú kan ní Nàìjíríà. Ṣùgbọ́n, o kì yóò jẹ́ ọmọ orílẹ̀ èdè […]

ẹ̀tọ́ọ̀ mi láti ní oun ìní

Lábẹ́ ọ̀rọ̀ òfin yìí, gbogbo ọmọ Nàìjíríà ni ó ní ẹ̀tọ́ láti rà tàbí ní dúkíà tó wà ní ojú kan àti èyí tó ṣe múrìn káàkiri ní Nàìjíríà. (44) (1) kòsí ẹni tó gbọ́dọ̀ fi ipá gba dúkíà ẹnikẹ́ni tó wà lójúkan tàbí tí o ń rìn láìṣẹ̀ nípa ọ̀nà tí òfin là kalẹ̀ […]

ẹ̀tọ́ọ̀ mi fún òmìnira lòdì sí ìyàsọ́tọ̀ ìkórìra

(1) Nítorí ẹ̀yà, ìlú, jíjẹ́ ọkùnrin tàbí obìnrin, ẹ̀sìn, èrò ènìyàn nípa òṣèlú, a kò gbọ̀dọ̀ ṣe àwọn ǹnkan wọ̀nyí fún àwọn ọmọ orílẹ̀ èdè yíì: a) ìṣe ojúsajú tàbí ìyanje fún enìkan tí a kò ṣe sí ẹnìkejì nítorí ọ̀rọ àgbègbè kan, ẹ̀yà, ìlú, ìjẹ́ ọkùnrin tàbí obìnrin, ẹ̀sìn tàbí èrò nípa òṣèlú rẹ̀. […]

ẹ̀tọ́ọ̀ mi fún òmìnira láti rìn káàkiri

(1) Gbogbo ọmọ Nàìjíríà ni o ní ẹ̀tọ́ láti rìn káàkiri Nàìjíríà àti láti gbé ní agbegbè Nàìjíríà. Kòsí ọmọ orílẹ̀ èdè yíì tí a gbọ̀dọ̀ mú kúrò ní Nàìjíríà tàbí dènà rẹ̀ láti wọlé tàbí jáde kúro ní Nàìjíríà. 2) kòsí ǹnkankan nínu apá kékeré òfin àkọkọ́ (1) yíì tó tako òfin tí ó […]

ẹ̀tọ́ọ̀ mi láti kórajọ ní àlàfíà àti láti bá ènìyàn kẹ́gbẹ́ pọ̀

gbogbo ènìyàn ló ní ẹ̀tọ́ láti kóra jọ ní ìrọrùn àti darapọ̀ láti dá ẹgbẹ́ òṣèlú sílẹ̀, ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́, tàbí ẹgbẹ́ míìràn fún ààbò ànfàní wọn. Ìdí fún ẹ̀tọ́ yìí nínu apá ọ̀rọ̀ iwé òfin yìí kò gba agbára ti ìwé òfin yìí fún Àjọ Elétò Ìdìbò INEC lóri àwọn ẹgbẹ́ òṣèlú èyi tí kò […]

ẹ̀tọ́ọ̀ òmìnira mi láti sọ àti ti ìròhìn

(1) gbogbo ènìyàn ló ní ẹ̀tọ́ láti fi ọ̀kàn rẹ̀ hàn àti ìwòye, ó lè gbà tàbí fúnni ní èrò tàbí ìròyìn láì dá dúró. 2) pẹ̀lú ọ̀rọ̀ ìwé òfin yìí, gbogbo ènìyàn ni o ní ẹ̀tọ́ láti ṣe ìdasílẹ̀ àti ṣíṣe iṣẹ́ ohun ìgbé ìròyìn àti ẹ̀rọ síta ní ọ̀nà wí pé: Kòsí ẹnikẹ́ni […]

ẹ̀tọ́ọ̀ mi fún òmìnira èrò, ọkàn àti ẹ̀sìn

(1) gbogbo ènìyàn ni ó ní ẹ̀tọ́ láti ronú tàbí ìwoye tó wù, tàbí yan ẹ̀sìn, yíì ẹ̀sìn rẹ̀ padà, tàbí ṣe ẹ̀sìn àti ìpòlongo ẹ̀sìn pẹ̀lú àwọn ènìyàn tàbí tìkara rẹ̀ nípasẹ̀ ìwásù, ẹ̀kọ́, tàbí ìjọsìn. 2) kòsí ilé ìwé tó gbọ́dọ̀ fi ipá mú akẹ́ẹ̀kọ̀ láti gba ìlanà ẹ̀sìn tàbí kópa nínu àjọyọ̀ […]

ẹ̀tọ́ọ̀ mi fún gbígbọ̀ tẹnu mìi láìsí ojùsàájú

(1) Láti ṣe ìdajọ́ lóri ẹ̀tọ́ àti ojúṣe ọmọ Nàìjíríà, ẹni náà gbọ́dọ̀ ní ànfàní láti sọ ti ẹnu rẹ̀ ní àsìkò tó mọ́gbọ́n wá ní ilé ẹjọ́ tàbí àjọ ìdajọ́. (2) Ṣùgbọ́n, a kò gbọ̀dọ̀ sọ wí pé òfin kò múnádóko tóri wí pé o fún ìjọba tàbí aṣàkoso ní agbára láti ṣe ìgbẹ́jọ́ […]

ẹ̀tọ́ tó fún mi ní òmìnira

(1) gbogbo ènìyàn ló ní ẹ̀tọ́ láti káàkiri àti wí pé a kò gbọdọ̀ dá òmìnira ẹnikẹ́ni dúró àyàfi ní àwọn ọ̀nà wọ̀nyí tí òfin làkalẹ̀: a) tí ẹni náà bá gba ìdajọ́ ilé ẹjọ́ torí wí pé ó jẹ̀bi ẹ̀ṣùn ìwà búburú; b) tí ẹni náà bá kùnà sí àṣẹ ilé ẹjọ́ tàbí tí […]