ẹ̀tọ́ọ̀ mi fún òmìnira láti rìn káàkiri
(1) Gbogbo ọmọ Nàìjíríà ni o ní ẹ̀tọ́ láti rìn káàkiri Nàìjíríà àti láti gbé ní agbegbè Nàìjíríà. Kòsí ọmọ orílẹ̀ èdè yíì tí a gbọ̀dọ̀ mú kúrò ní Nàìjíríà tàbí dènà rẹ̀ láti wọlé tàbí jáde kúro ní Nàìjíríà.
2) kòsí ǹnkankan nínu apá kékeré òfin àkọkọ́ (1) yíì tó tako òfin tí ó ṣe pàtàkì ní àgbègbè àwarawa bí:-
- a) kí wọ́n ṣe ìdaduró tàbí láti ma ṣe ìrìn káàkiri ènìyàn tó wùwà ọ̀daràn tàbí tí wọ́n fura sí wí pé ó dáràn láti máṣe gbà láyè láti sá kúrò ní Nàìjíríà.
- b) bí kí wọ́n dá ènìyàn padà láti Nàìjíríà lọsi orílẹ̀ èdè míìràn:
(i) láti kọju ìgbẹ̀jọ́ ìwà ọ̀daràn tí wọ́n fi kàn, tàbí
(ii) láti ṣẹ̀wọ̀n fún ìdajọ́ lórílẹ̀ èdè míìràn tí o ti dáràn tó tún jẹ̀bi ní orílẹ̀ èdè ti Nàìjíríà bá ní àdéhùn lórí irúfẹ́ ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀.