ẹ̀tọ́ọ̀ mi fún òmìnira lòdì sí ìyàsọ́tọ̀ ìkórìra
(1) Nítorí ẹ̀yà, ìlú, jíjẹ́ ọkùnrin tàbí obìnrin, ẹ̀sìn, èrò ènìyàn nípa òṣèlú, a kò gbọ̀dọ̀ ṣe àwọn ǹnkan wọ̀nyí fún àwọn ọmọ orílẹ̀ èdè yíì:
- a) ìṣe ojúsajú tàbí ìyanje fún enìkan tí a kò ṣe sí ẹnìkejì nítorí ọ̀rọ àgbègbè kan, ẹ̀yà, ìlú, ìjẹ́ ọkùnrin tàbí obìnrin, ẹ̀sìn tàbí èrò nípa òṣèlú rẹ̀.
- b) ṣíṣe ojúṣajú ní ọ̀nà tí àwọn míìràn kò rígbà ní àgbègbè kan nítorí ẹ̀yà, ìlú abínibí, ìjẹ́ ọkùnrin tàbí obìnrin tàbí èrò nípa ọ̀rọ̀ òṣèlú.
2) kòsí ọmọ Nàìjíríà kan tí a gbọ́dọ̀ fi ẹ̀tọ́ rẹ̀ dùn torí ipò bí wọ́n ṣe bi.
(3) kòsí ohun kankan ní apá kékeré àkọkọ́ (1) òfin yìí tí ó ṣe ìyẹpẹrẹ òfin míìràn tó fi òdinwọ̀n sí ìyànsípò àwọn ènìyàn sí ipò lábẹ́ ìjọba tàbí ti Ológun tàbí ti Ọlọ́pà tàbí ipò ilé iṣẹ́ tí ó di àgbékalẹ̀ lábẹ́ òfin Nàìjíríà.