ẹ̀tọ́ọ̀ mi láti wà láyé
(1) Gbogbo ènìyàn lóní ẹ̀tọ́ láti wà láyé àti wí pé kòsí ẹni tó gbọ́dọ̀ gba ẹ̀mí enikejì àyàfi tí ẹni náà bá gba ìdajọ́ ikú fún ìwà búburú tó lòdì sí òfin, tí ilé ẹjọ́ sì ri wí pé ó jẹ̀bi ẹ̀sùn náà.
(2) ẹni tó bá fi ipá kọlu ẹni kejì tí wọ́n si fi ìwọ̀n irú ipá bẹ́ẹ̀ lábẹ́ òfin kọlù tósì kú, a kò lè sọ wí pé wọ́n pa irú ẹni bẹ́ẹ̀. Irú èyí tí òfin fi ayè gbà nìwọ̀nyí:
- a) tí ó bá ṣẹlẹ̀ ní ìgbà tí enìkan ń gbìyànjú láti májẹ̀ kí ológbè fi ipá ṣe ẹnìkejì léṣe tàbí ba ohun ìní ẹnìkejì jẹ́
- b) ní ìgbà tí wọ́n bá fẹ́ fi òfin mú ológbè náà tàbí da dúro tó bá fẹ́ sálọ nínu àtìmọ́lé tó bá òfin mu
- c) nígbà tí wọ́n ba ń ṣe ìdádúró ìdàlùrú tàbí jàgídíjàgan.
ẹ̀tọ́ tó fún mi ní àpọ́nlé gẹ́gẹ́ bí ọmọ ènìyàn
(1)Gbogbo ènìyàn ni ó gbọ́dọ̀ ní owó àti wí pé:
(a) kòsí ẹni tí wọ́n gbọ́dọ̀ fún ní ìyà ìrora tàbí ìpalára búbúrú
(b) kòsí ẹni tí wọ́n gbọ́dọ̀ fi sí pamọ́ bí ẹrú
(c) kòsí ẹni tí wọ́n gbọ́dọ̀ fi ṣe iṣẹ́ ipá tí ó lòdì sí ìfẹ́ rẹ̀
(2) lábẹ́ apá òfin yìí, iṣẹ́ ipá kò kan àwọn àlàkalẹ̀ wọ̀nyí:
(a) Iṣẹ́ ipá tí ilé ẹjọ́ dá fún ẹni tó jẹ̀bi ẹ̀sùn;
(b) Iṣẹ́ ipá tí o maa ń wáyé látàrí iṣẹ́ àwọn ọmọ ẹgbẹ́ Ológun;
(c) iṣẹ́ ipá míìràn fún ẹni tó kọ̀ láti darapọ̀ pẹ̀lú ọmọ ẹgbẹ́ ológun;
(d) iṣẹ́ ipá míìràn tó ṣe pàtàkì torí pàjáwìrì tàbí ohun tó lè gba ẹ̀mí tàbí fún àlááfíà àgbègbè; tàbí
(e) Iṣẹ́ ipá tó wà lára ìwọ̀nyí:
- i) iṣẹ́ àgbègbè fún àlààfíà àgbègbè náà
- ii) iṣẹ́ tó jẹ́ dandan ní àjọ Ológun Nàìjíríà bí òfin Ilé Ìgbìmọ̀ Aṣòfin Àgbà ti ṣe wí
iii) iṣẹ́ tó jẹ́ dandan fún orílẹ̀ èdè yíì bí ìdánilẹ́kò fún àwọn ọmọ Nàìjíríà bí òfin ilé Ìgbìmọ̀ Aṣòfin Àgbà ti ṣe wí.